Nàìjíríà

Orílẹ̀-èdè Olómìnira Àpapọ̀ ilẹ̀ Nàìjíríà
Republik Nijeriya
Njíkötá Óchíchìiwù Naíjíríà (Ígbò)
Republik Federaal bu Niiseriya (Fula)
Federal Republic of Nigeria (Gẹ̀ẹ́sì)
جمهورية نيجيريا(Haúsá)
Àsìá Àmì ọ̀pá àṣẹ
Motto"Ìṣọ̀kan àti Ìgbàgbọ́, Àláfìà àti Ìlọsìwájú"
Orin-ìyìn orílẹ̀-èdè"Dìde, ẹ̀yin ará"
OlúìlúAbùjá
ilú títóbijùlọ Èkó
Èdè àlòṣiṣẹ́ Gẹ̀ẹ́sì, Haúsá, Ígbò, Yorùbá
Àwọn èdè dídámọ̀ níbẹ̀ Àwọn èdè Nàìjíríà
Orúkọ aráàlú Ará Nàìjíríà
Ìjọba Ààrẹ orile-ede olómìnira onijobapo
 -  Ààrẹ Mùhammádù Bùhárí
 -  Igbakeji Aare Yemi Osinbajo
 -  Àarẹ Ilé Alàgbà Bukola Saraki
 -  Agbẹnusọ Ilé Aṣojú Yakubu Dogara
 -  Olùdájọ́ Àgbà W.S. Nkanu Onnoghen
Ilominira latowo Britani 
 -  Isodokan Apaguusu ati Apaariwa Naijiria latowo Frederick Lugard 1914 
 -  Fifilole ati didamo October 1, 1960 
 -  Fifilole gege bi olominira October 1, 1963 
Ààlà
 -  Àpapọ̀ iye ààlà 923,768 km2 (32nd)
356,667 sq mi 
 -  Omi (%) 1.4
Alábùgbé
 -  Ìdíye 2009 154,729,000[1] (8th)
 -  Ìṣúpọ̀ olùgbé 167.5/km2 (71st)
433.8/sq mi
GIO (PPP) ìdíye 2011
 -  Iye lápapọ̀ $408.342 billion[2] 
 -  Ti ẹnikọ̀ọ̀kan $2,445 
GIO (onípípè) Ìdíye 2011
 -  Àpapọ̀ iye $267.779 billion[2] 
 -  Ti ẹnikọ̀ọ̀kan $1,603 
Gini (2003) 43.7 (medium
HDI (2010) 0.423[3] (low) (142nd)
Owóníná Nigerian naira (₦) (NGN)
Àkókò ilẹ̀àmùrè WAT (UTC+1)
 -  Summer (DST) ko si (UTC+1)
Ìwakọ̀ ní ọwọ́ ọ̀tún
Àmìọ̀rọ̀ Internet .ng
Àmìọ̀rọ̀o tẹlifóònù 234
1 Estimates for this country explicitly take into account the effects of excess mortality due to AIDS; this can result in lower life expectancy, higher infant mortality and death rates, lower population and growth rates, and changes in the distribution of population by age and sex than would otherwise be expected.² The GDP estimate is as of 2006; the total and per capita ranks, however, are based on 2005 numbers.

Nàìjíríà (pípè /naɪˈdʒɪrɪə/) tó jẹ́ mìmọ̀ fún ibiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bíi Orílẹ̀-èdè Olómìnira Àpapọ̀ ilẹ̀ Nàìjíríà (Nigeria ni èdè Gẹ̀ẹ́sì) jẹ́ orílẹ̀-èdè ìjọba àpapọ̀ olómìnira pẹ̀lú ìlànà-ìbágbépọ̀, to je pinpin si ìpínlẹ̀ mẹ́rindínlógójì àti Agbègbè Olúìlú Ìjọba Àpapọ̀. Ó bùdó sí apá ìwọ̀òrùn Afrika. Ilẹ̀ rẹ̀ ní bodè mọ́ Benin ní apá ìwọ̀òrùn, Nijẹr ní apá àríwá, Tshad àti Kamẹróòn ní apá ìlàòrùn àti Òkun Atlantiki ni apá gúúsù. Abuja ni olúìlú rẹ̀. Botilejepe ile Naijiria ni eya awon eniyan pupo, awon meta ni won tobijulo, ti won si pojulo. Awon wonyi ni Hausa, Ígbò ati Yorùbá.

Àwọn ará Nàìjíríà ní ìtàn fífẹ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni ẹ̀rí ìmọ̀-aíyejọ́un fihàn pé àwọn ìgbé ènìyàn ní agbègbè ibẹ̀ lọ sẹ́yìn dé kéré pátápátá ọdún 9000 kJ.[4] Agbegbe Benue-Cross River je riro gege bi ile akoko awon Bantu arokere ti won fan ka kiri opo arin ati apaguusu Afrika bi iru omi ni arin egberundun akoko kJ ati egberundun keji.

Oruko Naijiria wa lati Odò Ọya, to tun je mimo gege bi Odo Naija, eyi to san gba Nigeria koja. Flora Shaw, ti yio je iyawo lojo waju fun Baron Lugard ara Britani to je olumojuto amusin, lo seda oruko yi ni opin orundun 19sa.

Naijiria ni orile-ede to ni onibugbe pupojulo ni Afrika, ikejo ni agbaye[1], be si ni o je orile-ede to ni awon eniyan alawodudu julo laye. O je kikojo mo ara awon orile-ede ti a n pe "Next Eleven" ni to ri okowo won, o si tun je ikan ninu Ajoni awon Ibinibi. Okowo ile naijiria je ikan ninu eyi to n dagba kiakiajulo laye, pelu IMF to ngbero idagba 9% fun 2008 ati 8.3% fun 2009.[5][6][7][8] Ni ibere awon odun 2000, ogunlogo awon onibugbe gbe pelu iye to din ju US$ 1.25 (PPP) lojumo.[9] Naijiria ni okowo re tobijulo ni Afirika, ati alagbara ni agbegbe Iwoorun Afirika.

Ìtàn
Ere Nok ni Museomu Louvre, Paris.

Awon ara Nok ni arin Naijiria seso ere gbigbe alamo ti awon onimo ayejoun ti wari.[10] Ere Nok to wa ni Minneapolis Institute of Arts, juwe eni pataki kan to mu "opa idaran" dani ni owo otun ati igi ni owo osi. Iwonyi ni ami-idamo alase to je bibasepo mo awon farao ile Egypti ayeijoun ati orisa, Osiris, eyi lo n so pe iru awujo, idimule, boya ati esin ile Egypti ayeijoun wa ni agbegbe ibi ti Naijiria wa loni ni igba awon Farao.[11]

Ni apa ariwa, Kano ati Katsina ni itan akosile ti ojo won deyin to bi odun 999 kJ. Awon ilu-oba Hausa ati Ile-oba Kanem-Bornu gbooro gege bi ibudo aje larin Ariwa ati Iwoorun Afrika. Ni ibere orundun 19sa labe Usman dan Fodio awon ara Fulani di awon olori Ile-oba Fulani lojukan eyi to duro bayi titi di 1903 nigbati awon je pinpin larin awon olumusin ara Europe. Larin 1750 ati 1900, ida kan si ida meji ninu meta awon onibugbe awon ilu Fulani je eru nitori ogun.[12]

Ere lati Bini je eso ile Naijiria to gbajumo ati didamo julo

Awon Yoruba se ojo ti won ti wa ni agbegbe Naijiria, Benin ati Togo ayeodeoni seyin de bi odun 8500 kJ. Awon ilu-oba Ife ati Oyo ni apa iwoorun Naijiria gbale ni 700-900 ati 1400 nitelera won. Sibesibe, itan ariso Yoruba gbagbo pe Ile-Ife ni orisun eda eniyan pe be si ni o siwaju asa-olaju miran. Ife seso ere alamo ati onitanganran, Ilu-oba Oyo si fe de ibi ti Togo wa loni. Ilu-oba miran to tun gbale ni guusu apaiwoorun Naijiria ni Ilu-oba Benin lati orundun 15ru ati 19sa. Ijoba won de Ilu Eko ki awon ara Portugal o to wa so ibe di "Lagos."[13]


Ni apa guusuilaorun Naijiria, Ilu-oba Nri ti awon Igbo gbooro larin odunrun 10wa titi de 1911. Eze Nri ni o joba Ilu-oba Nri. Ilu Nri je gbigba gege bi ipilese asa igbo. Nri ati Aguleri, nibi ti itan ariso ida Igbo ti bere, wa ni agbegbe iran Umueri, awon ti won so pe iran awon de ile oba Eri fun ra re.[14]

Ìgbà Àmúsìn

Benin city in the 17th century with the Oba of Benin in procession. This image was pictured in a European book, Traduite du Flamand, in 1668.[15]

Awon oluwakiri ara Portugal ni awon ara Europe akoko to bere isowo ni Naijiria ti won si so ebute ni Eko di Lagos fun oruko ilu Lagos ni Algarve. Oruko yi le mo ibe bi awon ara Europe miran na se n se owo nibe. Awon ara Europe sowo pelu awon eya abinibi ni eba odo, won si bere owo eru nibe, eyi to pa opo awon eya abinibi Naijiria lara. Leyin ti awon ogun Napoleon bere, awon ara Britani fẹ isowo de inu arin Naijiria.

Ni 1885 igbesele Iwoorun Afrika latowo awon ara Britani gba idamo kariaye, nigba to si di odun to tele ile-ise Royal Niger Company je hihaya labe ayeolori Sir George Taubman Goldie. Ni 1900 awon ile ti ile-ise yi ni di ti ijoba Britani. Ni January 1, 1901 Naijiria di ile alaabo ti Britani, ikan ninu Ile-oba Britani to je alagbara julo nigba na.

Ni 1814, agbegbe na je sisodokan gege bi Imusin ati alaabo ile Naijiria (Colony and Protectorate of Nigeria). Fun amojuto, Naijiria je pinpin si igberiko apaariwa ati apaguusu ati imusin Eko. Eko Iwoorun ati okowo ayeodeoni tesiwaju ni kikankikan ni guusu ju ni ariwa lo, ipa eyi n han ninu aye oloselu Naijiria de oni. Ni odun 1936 ni oko eru sese di fifofin lu.[16]

Leyin Ogun Agbaye Eleekeji gege bi esi fun idagba isonibinibi Naijiria ati ibere fun ominira, awon ilana-ibagbepo to ropo ara won ti won je sisodofin latowo Ijoba Britani mu Naijiria sunmo ijoba-araeni to duro lori asoju ati apapo. Nigba to fi di arin orundun 20ji iru nla fun ominira ja ka kiri Afrika.

Leyin ominira

Ni October 1, 1960 Naijiria gba idani lowo orile-ede Sisodokan Ilu-oba. Ile olominira tuntun yi mu opo awon eniyan ti won n fe ki ibinibi ti won o je eyi to lagbara julo. Ijoba aladani Naijiria tuntun je isowopo awon egbe amojeoyipada: Nigerian People's Congress egbe to je didari lowo awon ara Ariwa ati awon elesin musulumi ti Ahmadu Bello ati Abubakar Tafawa Balewa to di Alakoso Agba akoko leyin ominira, je olori, ati eyi ti awon Igbo ati elesin Kristi je didari National Council of Nigeria and the Cameroons (NCNC) ti Nnamdi Azikiwe, to di Gomina-Agba ainibi akoko ni 1960, se olori. Ni ipo alatako ni egbe ilosiwaju Action Group (AG) ti o je didari lowo awon Yoruba ti Obafemi Awolowo se olori.[17]

Ipinu odun 1961 fun Apaguusu Kameroon lati darapo mo orile-ede Kameroon nigbati Apaariwa Kameroon duro si Naijiria fa aidogba nitori pe apa ariwa wa je titobi ju apaguusu lo gidigidi. Naijiria pinya lodo Britani ni 1963 nipa siso ara re di ile Apapo Olominira, pelu Azikiwe gege bi Aare akoko. Rogbodiyan sele ni Agbegbe Apaiwoorun leyin idiboyan 1965 nigbati Nigerian National Democratic Party gba ijoba ibe lowo AG.

Ijoba ologun akoko

Aidogba yi ati ibaje eto idiboyan ati oloselu fa ni 1966 de awon ifipagbajoba ologun lera lera. Akoko sele ni January ti awon odo oloselu alapaosi labe Major Emmanuel Ifeajuna ati Chukwuma Kaduna Nzeogwu. O ku die ko yori si rere - awon olufipagbajoba pa Alakoso Agba, Sir Abubakar Tafawa Balewa, Asolori Agbegbe Apaariwa Naijiria, Sir Ahmadu Bello, ati Asolori Agbegbe Apaiwoorun ile Naijiria, Sir Ladoke Akintola. Botileje bayi, sibesibe awon olufipagbajoba na ko le gbe ijoba kale nitori isoro bi won yio ti se, nitori eyi Nwafor Orizu, adelede Aare je mimu dandan lati gbe ijoba fun Ile-ise Ologun Adigun Naijiria labe Apase Ogagun JTY Aguyi-Ironsi.

Ijoba ati iselu

Sistemu ofin otooto merin lo wa ni Naijiria.

  • Ofin Ilegeesi, to wa lati igba amusin lowo Britani.
  • Ofin towopo, to je didagbasoke leyin amusin.
  • Ofin ibile, to wa lati inu awon asa ati ise kakiri ile naijiria.
  • Ofin Sharia

Naijiria ni eka idajo ti Ile-ejo Gigajulo ile Naijiria je eyi to lagbarajulo.

Ibasepo Okere

Àwọn ológun tó ń dojú ìjà kọ Boko Haram.

Ojuse awon ise ologun Olominira Apapo ile Naijiria ni lati daabo bo ile Naijiria, igbesoke ijelogun abo Naijiria ati itileyin itiraka igbero alafia agaga ni Iwoorun Afrika.

Ise ologun Naijiria ni Ile-ise Ologun Akogun, Ile-ise Ologun Ojuomi, ati Ile-ise Ologun Ojuafefe.

Lopolopo igba Ile-ise Ologun Naijiria ti ko ipa ninu igbero alafia ni Afrika. Ile-ise Ologun Naijiria gege bi ikan ninu ECOMOG ti ko ipa gege bi olugbero alafia ni Liberia ni 1990, Sierra Leone ni 1995, Ivory Coast ati Sudan.

Dimografiki

Naijiria ni orile-ede ti awon eniyan posijulo ni Afrika botilejepe iye gangan ko i je mimo. Agbajo Sisokan awon Orile-ede diye pe iye awon eniyan ni 2009 je 154,729,000, ti 51.7% inu won gbe loko ati 48.3% n gbe ni ilu ati iye eniyan 167.5 ni agbegbe ilopomeji kilomita kan.

Naijiria ni orile-ede kejo ti o ni awon eniyan topojulo laye. Idiye ni 2006 so pe iye eniyan ti ojo-ori won wa larin odun 0-14 je 42.3%, larin omo odun 15-65 je 54.6%. Osuwon ibimo po gidi ju osuwon iku lo, won je 40.4 ati 16.9 ninu 1000 eniyan ni telentele. Naijiria ni bi 250 eya eniyan pelu orisirisi ede pelu asa ati ise orisirisi. Awon eya eniyan totobijulo ni Hausa/Fulani, Yoruba ati Igbo ti apapo won je 68% nigbati Edo, Ijaw, Kanuri, Ibibio, Ebira, Nupe ati Tiv je 27%, awon yioku je 7%. Arin ibadi Naijiria je mimo pe o ni opolopo eya eniyan bi Pyem, Goemai, ati Kofyar.

Other Languages
Acèh: Nigeria
адыгабзэ: Нигерие
Afrikaans: Nigerië
Akan: Alata man
Alemannisch: Nigeria
አማርኛ: ናይጄሪያ
aragonés: Nicheria
Ænglisc: Nigeria
العربية: نيجيريا
অসমীয়া: নাইজেৰিয়া
asturianu: Nixeria
azərbaycanca: Nigeriya
تۆرکجه: نیجریه
башҡортса: Нигерия
Boarisch: Nigeria
žemaitėška: Nigerėjė
Bikol Central: Nigerya
беларуская: Нігерыя
беларуская (тарашкевіца)‎: Нігерыя
български: Нигерия
भोजपुरी: नाइजीरिया
Bahasa Banjar: Nigeria
bamanankan: Nijeria
བོད་ཡིག: ནི་ཇི་རི་ཡ།
বিষ্ণুপ্রিয়া মণিপুরী: নাইজেরিয়া
brezhoneg: Nigeria
bosanski: Nigerija
буряад: Нигери
català: Nigèria
Chavacano de Zamboanga: Nigeria
Mìng-dĕ̤ng-ngṳ̄: Nigeria
нохчийн: Нигери
Cebuano: Nigeria
ᏣᎳᎩ: ᏂᏥᎵᏯ
کوردی: نێجیریا
qırımtatarca: Nigeriya
čeština: Nigérie
Чӑвашла: Нигери
Cymraeg: Nigeria
dansk: Nigeria
Deutsch: Nigeria
Zazaki: Nicerya
dolnoserbski: Nigerija
डोटेली: नाइजेरिया
ދިވެހިބަސް: ނައިޖީރިއާ
eʋegbe: Naidzeria
Ελληνικά: Νιγηρία
English: Nigeria
Esperanto: Niĝerio
español: Nigeria
eesti: Nigeeria
euskara: Nigeria
estremeñu: Nigéria
فارسی: نیجریه
Fulfulde: Niiseriya
suomi: Nigeria
Võro: Nigeeriä
føroyskt: Nigeria
français: Nigeria
arpetan: Nig·èria
Nordfriisk: Nigeeria
Frysk: Nigearia
Gaeilge: An Nigéir
Gagauz: Nigeriya
贛語: 尼日利亞
Gàidhlig: Nìgeiria
galego: Nixeria
Avañe'ẽ: Nihéria
ગુજરાતી: નાઇજીરીયા
Gaelg: Yn Naigeer
Hausa: Nijeriya
客家語/Hak-kâ-ngî: Nigeria
עברית: ניגריה
हिन्दी: नाईजीरिया
Fiji Hindi: Nigeria
hrvatski: Nigerija
hornjoserbsce: Nigerija
Kreyòl ayisyen: Nijerya
magyar: Nigéria
հայերեն: Նիգերիա
interlingua: Nigeria
Bahasa Indonesia: Nigeria
Interlingue: Nigeria
Igbo: Naijiria
Ilokano: Nigeria
ГӀалгӀай: Нигери
Ido: Nigeria
íslenska: Nígería
italiano: Nigeria
Patois: Naijiiria
la .lojban.: nixerias
Basa Jawa: Nigéria
ქართული: ნიგერია
Qaraqalpaqsha: Nigeriya
Taqbaylit: Nijirya
Kabɩyɛ: Naajeeriya
Kongo: Nizeria
Gĩkũyũ: Nigeria
қазақша: Нигерия
ಕನ್ನಡ: ನೈಜೀರಿಯ
한국어: 나이지리아
kurdî: Nîjerya
kernowek: Nijeri
Кыргызча: Нигерия
Latina: Nigeria
Ladino: Nijeria
Lëtzebuergesch: Nigeria
лезги: Нигерия
Lingua Franca Nova: Nijeria
Luganda: Nigeria
Limburgs: Nigeria
Ligure: Nigeria
lumbaart: Nigeria
lingála: Nizeria
لۊری شومالی: نیجریٱ
lietuvių: Nigerija
latgaļu: Nigereja
latviešu: Nigērija
Malagasy: Nizeria
Baso Minangkabau: Nigeria
македонски: Нигерија
മലയാളം: നൈജീരിയ
монгол: Нигери
кырык мары: Нигери
Bahasa Melayu: Nigeria
Malti: Niġerja
مازِرونی: نیجریه
Nāhuatl: Nigeria
Plattdüütsch: Nigeria
Nedersaksies: Nigeria
नेपाली: नाइजेरिया
नेपाल भाषा: नाइजेरिया
Nederlands: Nigeria
norsk nynorsk: Nigeria
norsk: Nigeria
Novial: Nigeria
Sesotho sa Leboa: Nigeria
occitan: Nigèria
Livvinkarjala: Nigerii
ଓଡ଼ିଆ: ନାଇଜେରିଆ
Ирон: Нигери
ਪੰਜਾਬੀ: ਨਾਈਜੀਰੀਆ
Kapampangan: Nigeria
Papiamentu: Nigeria
Pälzisch: Nigeria
Norfuk / Pitkern: Niijiirya
polski: Nigeria
Piemontèis: Nigeria
پنجابی: نائیجیریا
português: Nigéria
Runa Simi: Niqirya
română: Nigeria
tarandíne: Nigerie
русский: Нигерия
русиньскый: Ніґерія
Kinyarwanda: Nijeriya
संस्कृतम्: नैजीरिया
саха тыла: Нигерия
ᱥᱟᱱᱛᱟᱲᱤ: ᱱᱟᱭᱡᱮᱨᱤᱭᱟ
sardu: Nigéria
sicilianu: Nigeria
Scots: Nigerie
davvisámegiella: Nigeria
Sängö: Nizerïa
srpskohrvatski / српскохрватски: Nigerija
Simple English: Nigeria
slovenčina: Nigéria
slovenščina: Nigerija
Gagana Samoa: Nigeria
chiShona: Nigeria
Soomaaliga: Nayjeeriya
shqip: Nigeria
српски / srpski: Нигерија
SiSwati: INayijeriya
Sesotho: Nigeria
Seeltersk: Nigeria
Basa Sunda: Nigéria
svenska: Nigeria
Kiswahili: Nigeria
ślůnski: Ńigeryjo
தமிழ்: நைஜீரியா
తెలుగు: నైజీరియా
тоҷикӣ: Нигерия
ትግርኛ: ናይጂሪያ
Türkmençe: Nigeriýa
Tagalog: Nigeria
Tok Pisin: Naijiria
Türkçe: Nijerya
Xitsonga: Nayjeriya
татарча/tatarça: Нигерия
ئۇيغۇرچە / Uyghurche: نىگېرىيە
українська: Нігерія
oʻzbekcha/ўзбекча: Nigeriya
vèneto: Nigeria
vepsän kel’: Nigerii
Tiếng Việt: Nigeria
West-Vlams: Nigeria
Volapük: Nigeriyän
walon: Nidjeria
Winaray: Nigeria
Wolof: Niseeria
吴语: 尼日利亚
isiXhosa: INigeria
მარგალური: ნიგერია
ייִדיש: ניגעריע
Vahcuengh: Nigeria
Zeêuws: Niheria
中文: 奈及利亞
文言: 尼日利亞
Bân-lâm-gú: Nigeria
粵語: 尼日利亞
isiZulu: INigeria